DURO, DURA FUN JESU

Ese: , 1858; a ko mo eniti to seitumo.

Orin: , 1830.


Duro, dura fun Jesu,
Enyin om’ogun Krist:
Gbe asia Re soke
A jo’gbodo fe ku;
Lat’isegun de ’segun
Ni y’o ma to ogun Re;
Tit’ao segun gbogb’ota,
Ti krist y’o j’Oluwa

Duro, duro fun Jesu
F’eti s’ohun ipe
Jade s’ohun ipe
L’oni ojo nla Re:
Enyin akin ti nja fun
Larin ainiye ota,
N’nu ewu, e ni ’gboiya
Dojuko agbara.

Duro, duro fun Jesu,
Duro l’agbara Re
Ipa enia ko to
Ma gbekele tire:
F’ihinrere hamora
Ma sona, ma gbadura
B’ise tab’ ewu ba pe
Ma se alai de ’be.

Duro, duro fun Jesu
Ija na ki y’o pe;
Oni, ariwo ogun,
Ola, orin ’segun,
Eni t’o ba si segun,
Y’o gba ade iye
Y’o ma ba Oba Ogo
Joba titi lailai…Amin