ODA MI LOJU MO NI JESU

Ese: , 1873; a ko mo eniti to seitumo.

Orin: .


Oda mi loju, mo ni Jesu!
Itowo adun oorun l’eyi je!
Mo di ajogun igbala nla,
Eje Re we mi, a tun mi bi.

Egbe

Ngo so itan na, ngo korin na,
Ngo yin Olugbala mi titi;
Ngo so itan na, ngo korin na,
Ngo yin Olugbala mi titi.

Ngo teriba fun tayotayo,
Mo le ri iran ogo bibo Re;
Angeli nmu ihin didun wa
Ti ife at’anu Re si mi.

Egbe

Ngo teriba fun, ngo simi le
Mo di ti Jesu, Mo d’eni ’bukun,
Ngo ma sora, ngo si gbadura,
Ki ore Re ma fi mi sile.

Egbe