OGO N’F’OLUWA

Ese: , 1875; a ko mo eniti to seitumo.

Orin: .


Ogo ni f’Oluwa, to se ohun nla;
Ifelo mu k’o fun wa ni Omo Re,
Eniti O f’emi Re lele fese wa,
To si silekun iye sile fun wa.

Egbe

Yin Oluwa, yin Oluwa,
F’Iyin fun Oluwa!
Yin Oluwa, yin Oluwa,
E yo ni waju Re!
K’a to baba wa lo, L’oruko Jesu,
Jek’a jo f’ogo fun Onise ’yanu.

Irapada kikun, ti eje Re ra,
F’enikeni t’ogba ileri Re gbo;
Enit’o buruju boba le gbagbo,
Lojukanna y’ori idari gba.

Egbe

O s’ohun nla fun wa, o da wa l’ola.
Ayo wa di kikun ninu Omo Re;
Ogo ati ewa Irapada yi
Y’oya wa lenu ’gbat’a ba ri Jesu.

Egbe