OJO IBUKUN Y’O SI RO!

Ese: , 1883; a ko mo eniti to seitumo.

Orin: .


“Ojo ibukun y’o si ro!”
Eyi n’ileri ife;
A o ni itura didun
Lat’ odo Olugbala.

Egbe

Ojo ibukun! Ojo ibukub l’a n fe
Iri anu wa yi wa ka, sugbon ojo l’a ntoro

“Ojo ibukun y’o si ro!”
Isoji iyebiye;
Lori oke on petele
Iro opo ojo m bo.

Egbe

“Ojo ibukun y’o si ro!”
Ran won si wa Oluwa!
Fun wa ni itura didun
Wa, f’ola fun oro Re.

Egbe

“Ojo ibukun y’o si ro!”
Nwon ’ba je le wa loni!
B’a ti njewo f’Olorun wa
T’a n pe oruko Jesu.

Egbe