OLUWA EMI SA TI GBOHUN RE

Ese: , 1875; a ko mo eniti to seitumo.

Orin: .


Oluwa, emi sa ti gbohun Re,
O nso ife Re si mi;
Sugbon mo fe dide lapa igbagbo
Kin le tubo sun mo O.

Egbe

Fa mi mora, mora Oluwa,
Sibi agbelebu t’Oku.
Fa mi mora, mora, Oluwa
S’ ibi eje Re to niye.

Ya mi si mimo fun ise tire,
Nipa ore-ofe Re;
Je ki nfi okan igbagbo woke,
K’ife mi le se Tire.

Egbe

A! ayo mimo ti wakati kan
Ti mo lo nib’ite Re,
’Gba mo ngbadura, si Olorun mi,
Ti a soro bi ore!

Egbe

Ijinle ife mbe ti nko le mo
Titi ngo koja odo;
Ayo giga ti emi ko le so
Titi ngo fi de ’sinmi.

Egbe