ORE WO L’A NI BI JESU

Ese: , 1855; a ko mo eniti to seitumo.

Orin: , 1868.


Ore wo l’ani bi Jesu, ti o ru banuje wa!
Anfani wo lo po bayi lati ma gbadura si!
Alafia pupo l’a nsonu, a si ti je rora po,
Tori a ko fi gbogbo nkan s’adura niwaju re.

Idanwo ha wa fun wa bi? A ha nni wahala bi?
A ko gbodo so ’reti nu; sa gbadura si Oluwa.
Ko s’oloto orebi re ti ole ba wa daro,
Jesu ti mo ailera wa; sa gbadura s’Oluwa.

Eru ha nwo wa l’orun bi, aniyan ha po fun wa?
Olugbala je abo wa, sa gbadura s’Oluwa.
Awon ore ha sa o ti? Sa gbadura s’Oluwa.