WA EYIN OLOOTO

Ese: A ko mo eni to se itumo si ede Yoruba.

Orin: John F. Wade.


Wa eyin olooto, Layo at’ isegun,
Wa ka lo, wa ka lo si Betlehem,
Wa ka lo wo o! Oba awon Angeli.

Egbe

E wa ka lo juba Re,
Ewa ka lo juba Re,
E wa ka lo juba
Kriti Oluwa.

Olodumare ni, Imole ododo,
kosi korira inu Wundia;
Olorun paapaa ni, Ti a bi, ti a ko da.

Egbe

Angeli e korin, Korin itoye re;
ki gbogbo eda orun si gberin:
Ogo f’Olorun Li oke orun.

Egbe

Ni tooto, a wole, F’Oba t’a bi loni;
Jesu iwo l’a wa nfi ogo fun:
’Wo omo Baba, To gba’ra wa wo.

Egbe